...fostering unity

among Yoruba people

...promoting the

teaching of Yoruba culture

...celebrating the

values of Yoruba

ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ, NÀÌJÍRÍÀ

Aare EgbeÌbà Ọlọ́run Olódùmarè ọba atẹ́rẹrẹkáríayé. Ọba tó ń fi ọba jẹ. Ọba Olùfinisípò tó ń jẹ́ káyé ó yẹni.
Adẹ́dàá tó ń fi ìrọ̀rùn òun àlàáfíà fún ẹ̀dá àti ohun gbogbo tí ó yíi ká.
Mo gbé òṣùbà ràbàǹdẹ̀ fún Ààrẹ àti gbogbo ọmọ ìgbìmọ̀ tí ó tukọ̀ Ẹgbẹ́ yìí ṣáájú mi pé pé iṣẹ́ ńlá ni ẹ ti ṣe.
Mo pá ìgúnwọ́mọ́ fún ẹ̀yin bàbá, màmá àti ẹ̀yin àgbààgbà nínú Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá ní Ilẹ̀ Nàìjíríà fún gbogbo ìlàkàkà àti àwọn iṣẹ́ takuntakun tí ẹ ti gbé ṣe láti mú Ẹgbẹ́ yìí tẹ̀síwájú dé oríta tí ó dé yìí.
Mo dúpẹ́ púpọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ yìí ní àwọn ìpínlẹ̀ wa gbogbo tí omi Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá sàn dé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wí pé Ẹgbẹ́ yìí yóò máa tẹ̀síwájú ní rere ní àsìkò àti ìgbà gbogbo wa láṣẹ Èdùmàrè.
Mo wá fi àsìkò yìí bẹ̀bẹ̀ àtìlẹyìn tí ó lóòrìn láti ọ̀dọ̀ gbogbo ẹ̀yin Bàbá, Màmá Àgbààgbà nínú Ẹgbẹ́ yìí láti má kàárẹ̀ mímú ìlọsíwájú bá Ẹgbẹ́ yìí nínú ojúṣe, ìdarí àrítọ́kasí àti fífa gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ lọwọ́ sókè nínú èyí tí ó le túbọ̀ máa mú orúkọ rere, ìgbéga àti ohun ọ̀tun bá Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá ní Ilẹ̀ Nàìjíríà.
Èròǹgbà mi gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ tuntun fún Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá ni pé ìgbéga Akọ́mọlédè àti orúkọ rere rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ àjọṣe gbogbo wa.
Ọlọ́run Olódùmarè yóò sì ṣe àtìlẹyìn fún àwa ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe tuntun tí ẹ fi ìbò yàn àti gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ fún ìdàgbàsókè iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá ní Ilẹ̀ Nàìjíríà.
Ire o.
Arábìnrin Fèyíṣìkẹ́ Aya Àlíù
Ààrẹ Ẹgbẹ́ 

+++++++++++++++++++++++++++++++++++++++++++++++
Gẹ́gẹ́ bí àwọn Onígbàgbọ́, a-tẹ̀lé-Kristi ti, ọkàn nínú àwọn orin tí Olóògbé Àlúfà Àgbà kan tí ó jẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá, tí a si ńpè ní Josiah Jesse Ransome-Kuti ti kọ̣ ní ohùn orin ti ilẹ̀ wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn báyìí pé:
Láàarin Osù Ogún Ọdún, Arákùnrin kan wà ní Ìbàdàn tí ó ti ńṣe iṣẹ́ Olùkọ́ni ní Ìbàdàn Boys’ High School, tí ó wà ní Òke Bọ́là ní Ìbàdàn, sùgbọ́n tí ó ti fi iṣẹ́ Olùkọ́ni sílẹ̀ tí ó sì ńṣe iṣẹ́ Olùkọ̀wé lóríṣìíríṣìí ọ̀nà láti ọ̀nà láti ran àwọn ọmọ Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga lọ́wọ́ nínú èdè Yorùbá. Nínú àwọn ìwé tí ó kọ nígbà náà ni “Ìgbáradì fún Ìdánwò Oníwèé Mẹ́wàá”  tí a mọ̀ sí West African Examination Council’s School Certificate tàbí General Certificate Examination (Ordinary Level).
N kò pàdé arákùnrin yìí rí, n kò sì mọ́ ọ́ rí, sùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún mi nígbà tí ó wá bá mi ní Ilé Ẹ̀kọ́  Gíga tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà náà tí à ń pè ní Èyínnì High School, Ibadan. Olóyè J.A. Ọlá Ọdẹ́bìyí, tí ó ti fi ìgbà kan jẹ́ Mínísítà ní Ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn lábẹ́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ni ó dá Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga yìí sílẹ̀.
Mo ní n kò mọ ẹni tí ó tọ́ka mi sí arákùnrin yìí pé mo ní ìfẹ́ èdè Yorùbá tó bẹ̀ẹ̀ nígbà náà. Àwọn Àgbà tàbí Ògbólógbòó Olùkọ́ni bíi èmi sáà wà ní Ìlú Ìbàdàn nígbà náà, sùgbọ́n ó dàbí ẹni pé ẹ̀mí Baba wa Odùduwà  ní ó darí  rẹẹ̀ sí mi.
Ó máa ń pàrà ọ̀dọ̀ mi gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹẹ̀ pé ó le ran òun lọ́wọ́ nínú èrò tí òun fẹ́ gbé jáde nipa Èdè Yorùbá nígbà náà.
Bíi ojoojúmọ́ ni ó máa ń wá tí ó sì ń rọ̀ mí láti dìde sí iṣẹ́ yìí láti dá ẹgbẹ́ Olùkọ́ni ní Èdè Yorùbá sílẹ̀ ní Ìbàdàn.

Nígbà tí mo fi ojú inú wo ọ̀rọ̀ náà, mo wòye pé iṣẹ́ ńlá ni yóò jẹ ní Ìlú ńlá bíi Ìbàdàn yìí. Sùgbọ́n nígbà tí ó tún dé mo ní kí ó wá fún èsì lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méjì, Ó gbọ́ ó sì lọ. Kò jẹ́ kí àsìkò yẹn pé kí ó tó tún padà wá, sùgbọ́n, èmi náà ti múra èsì tí n ó fún un sílẹ̀.

Read More →

Reviewed Publications

  • Ise Yoruba - Reviewed by Sobande Seyi
  • Asa ati Ede - Reviewed by Adedigba Sylvester
  • View All →

    Subscribe to Our
    Newsletter

    Quotable Quote

    The only person that is educated is the one that has learned how to learn and change. - Carl Rogers

    OÌ£wóÌ£ oÌ£moÌ£dé kò tó peÌ£peÌ£ ti àgbàlagbà kò woÌ£ kèrègbè

     

    Ewé kì í bóÌ£ lára igi kó ni igi lára ----- the dropping of a leaf off a tree presents no burden to the tree.

    © 2024 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Naijiria. All Rights Reserved.