ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀSÀ YORÙBÁ, NÀÌJÍRÍÀ
Ọdún 1969 ni ẹgbẹ́ yìí bẹ̀rẹ̀ ni sàn-án. Àwọn tó kọ́kọ́ tukọ̀ Ẹgbẹ́ yìí ni Adéyẹmọ Ọdẹ́lànà, Olóògbé Láyẹni Lásíji, Alàgbà Jíìre Ọjẹ́dìran. Àwọn yòókù tún ni olóògbé Adéyẹmọ Adérìnkòmí, Olóògbé Oyédèmí Oyèríndè, Olóògbé Babátúndé Ọlátúnjí, Arábìnrin Dúpẹ́ Babalọlá Arọ́mọláràn-án, Alágbà T.A.A. Ládélé. Gbogbo àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyìí ko gba oyè nínú ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá. Wọ́n ní ìfẹ́ sí èdè náà ni tí wọn sì fẹ́ kí ó máa dàgbà sókè síi. Olùkọ́ àgbà ní àwọn wọ̀nyí ní ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ onípò kejì àti ti girama nígbà náà.
Ẹ̀yìn tí àwọn wọ̀nyí tukọ̀ Ẹgbẹ́ ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Fẹ̀yìnti Olóyè Olúdáre Olájubù tó tẹ́wọ́ gba ìṣàkóso Ẹgbẹ́ tí Olóògbé Alhaji Oyèbánji Mustapha sì di Akọ̀wé. Ọ̀jọ̀gbọ́n-fẹ̀yìntì Ọmọ́táyọ̀ aya Olútóyè ló ṣe Àárẹ Ẹgbẹ́ lẹ́yìn Olóyè Ọlájubù kí Olóògbé Oyèbánjí tó gba ipò Ààrẹ tí Ọ̀mọ̀wé Délé Àjàyí sì di Akọ̀wé.
Ọwọ́ Olóògbé Oyèbánjí Mustapha ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúgbóyèga Àlàbá ti gba ìṣàkóso Ẹgbẹ́ tí òun náà sì gbée fún Ọ̀mọ̀wé Adémọ́lá Ọdẹ́tókun tí Alàgbà Ṣẹ́gun Ògúnfolájí jẹ́ Akọ̀wé. Ọwọ́ Ọ̀mọ̀wé Ọdẹ́tókun ni Alàgbà Túndé Ẹkúndayọ̀ tì gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ, tí Díákónì Akínwùmí Olówu sì jẹ́ Akọ̀wé.
Lẹ́yìn tí Alàgbà Túndé Ẹkúndayọ̀ tukọ̀ Ẹgbẹ́, ni Díákónì Akínwùmí Olówu tẹ́wọ́ gba ìsàkóso Ẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Àárẹ tí Aposteli Àgbà Abíọ́dún Oyèdèmí sì jẹ́ Akọ̀wé. Ọwọ́ Díákónì Akínwùmí Olówu ni Olóyè Díípọ̀ Gbénró ló tukọ̀ Ẹgbẹ́ bíi Àárẹ tán tí Àlúfàà Ayọ̀ Adésínà sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà bíi Ààrẹ, tí Díákónì Obìnrin Ọmọ́wùmí aya Fálẹ́yẹ sì jẹ́ Akọ̀wé. Àwọn méjèèjì ló sì ń tukọ̀ Ẹgbẹ́ náà lọ́wọ́lọ́wọ́.
ÀNÍYÀN ẸGBẸ́
Lára àwọn Àníyàn Ẹgbẹ́ wa ni pé:
1. Kí gbogbo Olùkọ́ Èdè Yorùbá parapọ̀ fún kíkọ́ Èdè, Àṣà àti Lítíréṣọ̀ Yorùbá ní àkóyege.
2. Kí àwa olùkọ́ wọ̀nyí lè máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jákèjádò ilẹ̀ wa lórí Èdè, Àṣà àti Lítíréṣọ̀ Yorùbá.
3. Kí àjọṣe tí ó báramu le wà láàrin ìlé iṣẹ́ tí ó ń darí ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
4. Kí ìdàgbàsókè tó péye le bá Èdè, Àṣà àti Lítíréṣọ̀ Yorùbá kí Èdè náà má baà parun láàrin àwọn akẹgbẹ́ rẹ lágbàáyé.
LÁRA ÀWỌN NǸKAN TÍ ẸGBẸ́ YÌÍ TI GBÉ ṢE:
1. Ẹgbẹ́ yìí tí kọ ìwé kíkà fún ilé-ẹ̀kọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ilé-ẹ́kọ̀ Girama ọlọ́dún mẹ́ta àkọ́kọ́ àti ilé-ẹ̀kọ́ Girama ọlọ́dún mẹ́ta kejì.
2. Ẹgbẹ́ yìí máa ń gbé Jọ́nà àtìgbàdégbà (Journal) tí a pè ní “YORÙBÁ GBÒDE” jáde ní ọdọọdun.
3. Ṣíṣe ìpàdé gbogbogboò Ẹgbẹ́ káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá lọ́dọọdún fún ìjíròrò lórí ìdàgbàsókè àti àfikún ìmọ̀ lórí Èdè àti Àṣà Yorùbá.
A máa ń ṣètò oríṣiríṣi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lóórèkóòrè láti rí i pé Àṣà wa kò di àtẹ̀mẹ́rẹ̀ àti pé ìmọ̀ wa nínú Èdè Yorùbá kò jọ́bà ní àwọn ìpínlẹ̀ wa gbogbo.
IṢẸ́ TÍ ẸGBẸ́ Ń ṢE LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́.
Bàbá wa Àgbà, Kábíyèsí Aláyélúwà, Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀, tí fí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sarè ilẹ̀ ta Ẹgbẹ́ wa lórẹ láti fi kọ́ ilé-ìsẹ̀ǹbáyé tí yóò jẹ oríko fún àwọn ọmọ Ẹgbẹ́. Ẹgbẹ́ sì tí ń gbé ìgbésẹ̀ láti kọ́ ilé náà.
BÍ A ṢE DÁ ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ SÍLẸ̀ (NÍ ÌBÀDÀN, NÀÌJÍRÍÀ)
Gẹ́gẹ́ bí àwọn Onígbàgbọ́, a-tẹ̀lé-Kristi ti, ọkàn nínú àwọn orin tí Olóògbé Àlúfà Àgbà kan tí ó jẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá, tí a si ńpè ní Josiah Jesse Ransome-Kuti ti kọ̣ ní ohùn orin ti ilẹ̀ wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn báyìí pé:
Ìgb’Olú bá ránṣẹ́…
Ìgb’Olú bá ránṣẹ́ o…
Gbogbo Ẹ́gbá á d’onígbàgbó ooo…
Ìgb’Olú bá ránṣẹ́…
Bákannáà ni a le wí nípa ti Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè wípé
Ìgb’Olú bá ránṣẹ́…
Ìgb’Olú bá ránṣẹ́ o…
Gbogbo Ayé á d’Onímọ̀-Ìjìnlẹ̀-Yorùbá ooo…
Ìgb’Olú bá ránṣẹ́…
Láàrin Osù Ogún Ọdún, Arákùnrin kan wà ní Ìbàdàn tí ó ti ńṣe iṣẹ́ Olùkọ́ni ní Ìbàdàn Boys’ High School, tí ó wà ní Òke Bọ́là ní Ìbàdàn, sùgbọ́n tí ó ti fi iṣẹ́ Olùkọ́ni sílẹ̀ tí ó sì ńṣe iṣẹ́ Olùkọ̀wé lóríṣìíríṣìí ọ̀nà láti ọ̀nà láti ran àwọn ọmọ Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga lọ́wọ́ nínú èdè Yorùbá. Nínú àwọn ìwé tí ó kọ nígbà náà ni “Ìgbáradì fún Ìdánwò Oníwèé Mẹ́wàá” tí a mọ̀ sí West African Examination Council’s School Certificate tàbí General Certificate Examination (Ordinary Level).
N kò pàdé arákùnrin yìí rí, n kò sì mọ́ ọ́ rí, sùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún mi nígbà tí ó wá bá mi ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà náà tí à ń pè ní Èyínnì High School, Ibadan. Olóyè J.A. Ọlá Ọdẹ́bìyí, tí ó ti fi ìgbà kan jẹ́ Mínísítà ní Ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn lábẹ́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ni ó dá Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga yìí sílẹ̀.
Mo ní n kò mọ ẹni tí ó tọ́ka mi sí arákùnrin yìí pé mo ní ìfẹ́ èdè Yorùbá tó bẹ̀ẹ̀ nígbà náà. Àwọn Àgbà tàbí Ògbólógbòó Olùkọ́ni bíi èmi sáà wà ní Ìlú Ìbàdàn nígbà náà, sùgbọ́n ó dàbí ẹni pé ẹ̀mí Baba wa Odùduwà ní ó darí rẹẹ̀ sí mi.
Ó máa ń pàrà ọ̀dọ̀ mi gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹẹ̀ pé ó le ran òun lọ́wọ́ nínú èrò tí òun fẹ́ gbé jáde nipa Èdè Yorùbá nígbà náà.
Bíi ojoojúmọ́ ni ó máa ń wá tí ó sì ń rọ̀ mí láti dìde sí iṣẹ́ yìí láti dá ẹgbẹ́ Olùkọ́ni ní Èdè Yorùbá sílẹ̀ ní Ìbàdàn.
Nígbà tí mo fi ojú inú wo ọ̀rọ̀ náà, mo wòye pé iṣẹ́ ńlá ni yóò jẹ ní Ìlú ńlá bíi Ìbàdàn yìí. Sùgbọ́n nígbà tí ó tún dé mo ní kí ó wá fún èsì lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méjì, Ó gbọ́ ó sì lọ. Kò jẹ́ kí àsìkò yẹn pé kí ó tó tún padà wá, sùgbọ́n, èmi náà ti múra èsì tí n ó fún un sílẹ̀.
Nígbà tí ó bèèrẹ̀ bí mo ti rò ó sí, mo sọ fún un pé bí ó bá ti le ṣe ìyọnu ìkéde rẹ̀ẹ̀, kí ó sì pe ìpàdé sí ibi tí àwọn ènìyàn le wá, mo ṣèlérí pé n ó ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ríi pé Ẹgbẹ́ náà fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa. Ó dúpẹ́, ó sì lọ.
Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan ó tún dé pẹ̀lú ìwé ìpèpàdé, ó fún mi ní tèmi, ó sì tún fún Olóyè Ọdẹ́bìyí ní tirẹ̀, nítorí abẹ́ Olóyè yìí ní mo ń ṣiṣé nígbà náà.
A fí ìpàdé èkínní sí Ọjọ́ kejì Osù Ọ̀wẹ̀wẹ̀ Odún 1968 ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga tí à ńpè ní Ìbàdàn Boy’s High School. Àwọn tí ó wa sí ìpàdé yìí lọ́jọ́ náà jẹ́ mẹ́ẹ̀dógún (15).
Láti Ìbàdàn…. 10 (pẹ̀lú àwọn Oníwèé Ìròyìn)
Láti Abà Ńlá…. 1
Láti Ìròkò (Ọ̀yọ́)…. 1
Láti Ìkirè …. 1
Láti Ìwó …. 1
Láti Òkehò …. 1
Lẹ́hìn tí a ti kí ara wa tán, tí a sì ti fi ara wa han ara wa tán, a yan Ọ̀gbẹ́ni Bọ́lá Adétúyì tí ó jẹ́ Olùkọ́ni ní Ahmadiyya Grammar School Elẹ́yẹlé, Ìbàdàn, gẹ́gẹ́ bíi Adelé Akọ̀wé. Òun ní ó jísẹ́ fún wa pé Ọ̀gbẹ́ni Adébísí Arọmọlaran kò le wá sí ìpàdé nítorí ìdíwọ́ kan. Iṣẹ́ tàbí ìwé tí Arọmọlaran fi rańṣẹ́ sí wa lọ báyìí pé:
The aims and purpose of the association were explained and discussed at length, and approved as follows
(a). To make all efforts in improving the standard of Yoruba Language in schools; to serve as a forum for problems in the teaching of the language could be discussed and solved.
(b). To organize regular seminars, lectures and excursions.
(c). To set up a show room/library in Ibadan where all Yoruba books - novels, poems, and text books could be inspected and approved for students’ use.
(d). To help teachers of Yoruba language, whenever they are in difficulties – to this end specialists in any aspect of the language should leave their addresses with the secretary; and teachers in difficulties could contact the secretary who will ask aa specialist to help the member school concerned.
(e). To assist intending writers and authors on Yoruba Language.
Lẹhìn èyí ni a ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí;
Membership
All teachers – in Grammar, Secondary, Commercial and Teacher Training Colleges, are to e members of the association.
Schools in each province should forma provincial branch of the association, which will meet frequently. Each provincial branch shall have a Chairman, a Secretary/Treasurer, and an Auditor.
All general meetings shall hold at Ibadan.
It was agreed after a protracted debate by a majority vote that members – schools shall contribute one guinea (21/-) as annual dues, in view of the association’s aims and activities.
Relationship With Ẹgbẹ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá
The association is in no way a rival or superior to the Ẹgbẹ Ijinlẹ Yoruba. In fact the two groups are to work hand in hand. While Ẹgbẹ Ijinlẹ Yoruba comprises of all Yoruba speaking elites both literate, the association of teachers of Yoruba Language is an assembly teachers and authors.
General
The following Yorùbá Language veterans are to be contacted:- Messrs A. Fálétí, Túndé Oloyede, J.A. Ọdẹ́lànà and Chiefs J.F. Ọdúnjọ and J.A. Ayọrinde.
Letters are to be written to the
(i). West African Examinations Council
(ii). All States Ministries of Education
(iii). Ẹgbẹ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá
(iv). Notable Yoruba authors and publishers
(v). Yoruba Language Department and Institute of African Language of the Nigerian Universities.
That motion “the association appreciates the efforts of Mr. Adébísí Aromọlaran in convening this meeting; and expresses its profound gratitude” was moved by Mr. Dayọ̀ Àró and seconded by Mrs. J. Shádékọ́ was unanimously adopted.
Election of Officers
It was agreed upon that 1969 Officers of the Association will be elected at the General Meeting of February 8th 1969.
It was agreed that the next General Meeting shall take place in Ibadan on Saturday, 8th February, 1969 at 11.00am in the School Hall of Ibadan Boy’s High School.
The Meeting was ended at about 1.30pm.
Nígbà tí ọjọ́ Àgan tí í ṣe Ọjọ́ kẹẹ̀jọ osù Èrèlé Ọdún 1969 pé, ẹsẹ̀ pé ju ti àkókó lọ, èrò pọ̀ gidi. Àwọn ohun pàtàkì tí a ṣe ni pé a yan àwọn Olóyè Ẹgbẹ́ pẹ̀lú ìbò dídì.
Arákùnrin wa Ọ̀gbẹ́ni A. Aromọlaran sì wá sí ìpàdé yìí, òun ni ó ṣe ètò láti yan ènìyàn pẹ̀lú:
Fún ipò Akọ̀wé Ẹgbẹ́, Ìbò mú Bọ́lá Adétuyì
Fún ipò Alága Ẹgbẹ́, Ìbò mú E.D. Akínbọ̀wálé
Fún ipò Igbákejì Alága, Ìbò mú J.A. Ọdélànà (Ọkùnrin)
Fún ipò Igbákejì Alága, Ìbò mú Mrs. Grace Ìgè (Obìnrin)
Fún Ipò Olùrànlọ́wọ́ Akọ̀wé, Ìbò mú Mrs. Sọlá Adégbọlá |