...fostering unity

among Yoruba people

...promoting the

teaching of Yoruba culture

...celebrating the

values of Yoruba

Ìpàdé Àpérò Ológójì Ọdún

Ọ̀RỌ̀ ÌKÍNI KÁÀBỌ̀ TÍ A KÀ NÍBI AYẸYẸ ÌSÍDE ÌPÀDÉ ÀPÉRÒ OLÓGÓJÌ ỌDÚN ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ NÀÌJÍRÍÀ TÍ Ó WÁYÉ NÍ FEDERAL GOVERNMENT COLLEGE ÒGBÓMỌ̀SỌ́, ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ NÍ ỌJỌ́ AJÉ, ỌJỌ́ KẸRIN, OṢÙ KẸJỌ ỌDÚN 2014 LÁTI ẸNU ÀÀRẸ ẸGBẸ́ - ÀLÙFÁÀ AYỌ̀ ADÉṢÍNÀ

ỌLỌ́LÁ WA

SẸ́NÉTỌ̀ ABÍỌ́LÁ ADÉYẸMÍ AJÍMỌ̀BI

GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YÓ

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N SOLOMON OLÁNÍYỌNU

KỌMÍSÁNNÀ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́

ALÁGA ÀJỌ ÀWỌN OLÙKỌ́ SẸ́KÓŃDÍRÌ (TESCOM)

ALÁGA ÈTÒ ÈKỌ́́ KÁRÍAYÉ

KỌMÍṢÁNNÀ ÈTÒ ÀṢÀ ÀTI Ọ̀RỌ̀ ÌGBAFẸ́

OLÙBÁDÁMỌ̀RÀN GÓMÌNÀ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ÀṢÀ

KÁBÍYÈSÍ, ṢỌ̀UN TÍ ÒGBÓMỌ̀ṢỌ́

GBOGBO Ẹ̀YIN ORÍADÉ YÒÓKÙ PÁTÁ TÓ WÀ NÍKÀLẸ̀

TÓTÓTÓ BÍ ARÓ

MO SÚN MỌ́BA NÍWỌ̀N EBÈ KAN

MO JÌNÀ SỌ́BA NÍWỌ̀N LÉBÈ MÉJÌ

N Ò JẸ́ RỌ́BA FÍN O

ARỌ́BA FÍN LỌBÁ PA

MÁ PA MÍ O, ỌBA Ẹ DÁKUN

ẸṢIN ỌBA YÓÒ JẸKO PẸ́

ÌRÙKẸ̀RẸ̀ YÓÒ LE SI

IGBA ỌDÚN ỌDÚN KAN

Ọ̀GÁ ILÉ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÀTI ÌDÀGBÀSÓKÈ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ (NERDC)

Ọ̀GÁ ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń ṢÈTÒ ÌDÁNWÒ ONÍWÈÉ MẸ́WÀÁ (WAEC)

Ọ́GÁ ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń ṢÈTÒ ÌDÁNWÒ ONÍWÈÉ MẸ́WÀÁ (NECO)

Ẹ̀YIN AGBÓHÙN SÁFẸ́FẸ́ ÀTI ONÍWÈÉ ÌRÒYÌN

Ẹ̀YIN ỌMỌ ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀGBÁÁLA AYÉ

Ẹ̀YIN Ọ̀RẸ́ WA GBOGBO

Ẹ̀YIN ẸGBẸ́ AMÚLÙÚDÙN YÒÓKÙ TÓ Ń LÉPA ÌDÀGBÁSÓKÈ ÀṢÀ ÀTI ÌṢE YORÙBÁ TÓ WÀ NÍBÍ TÍ N KÒ DÁRÚKỌ

AKỌ́MỌLÉDÈ – TIWA LÀṢÀ ỌMỌLÚÀBÍ

AKỌ́MỌLÁṢÀ – TIWA LÈDÈ ỌMỌLÚÀBÍ

A dúpẹ́ tí a ò yọ sọnù bíi ọmọ ọwọ̀

A dúpẹ́ tí a o kú sọ́nà bí èéfin

A dúpẹ́ o Èdùmàrè

Táráayé ò f’ẹgbẹ́ wa pìtàn láábi

Ẹ jẹ́ kí gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ ó fìbà f’Élédùmarè:

Kò sí ẹni tó ni gbogbo ọpẹ́ yìí bí ò bá jẹ́ Olódùmarè Ọba atẹ́nílẹgẹ́lẹgẹ́ fórí sagbeji, ọba alábẹ́nu àá sá sí, Ọba oníyẹ̀ẹ́ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ. Ká bi ọ́ ò sí, ọba mímọ́. Mo ṣèbà o, mo ṣèbà gbogbo ènìyàn tí ń bẹ́ níkàlẹ̀. Ọ̀pọ̀ òjò ló ti rọ̀ tílẹ̀ ti fi mu, ṣùgbọ́n nínú Ẹgbẹ́ olókìkí yìí, Ẹgbẹ́ olóríire yìí, orin ọpẹ́ kò kúrò lẹ́nu wa, ìlù ọpẹ́ kò kúrò lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ sì ni, ijó ẹpẹ́ kò kúrò lẹ́sẹ̀ wa.

 

Kì í ṣe pé àṣamọ̀ mí pọ̀, ohun tí ọ̀pọ̀ ọmọ Ẹgbẹ́ wa yìí mọ̀ ni, sùgbọ́n ó le ṣóòkùn sí ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níkàlẹ̀. Ẹ dákun, ẹ jẹ́ kí n làá hàn yín bí bàtá tii ń ké lótù Ifẹ̀. Ọdún yìí ló pé ogójì ọdún tí Ẹgbẹ́ wa ti ń ṣe ìpàdé Àpérò àti ìpàdé Gbogbogboò. Ìdí nìyí tí inú gbogbo wa fi ń dùn, tí a tún wá fi aṣọ Àńkárá tí ẹ̀ ń wò lọ́rùn wa yìí sàmì ayẹyẹ ogójì ọdún náà. Ṣé ẹ wá rí i pé ọ̀rọ̀ wa tọ́pẹ́, ó ju ọpẹ́ lọ.

Akọ́mọlédè-------------

Akọ́mọláṣà-------------

 

A dúpẹ́ lọ́dọ̀ Adẹ́dàá pé Ẹgbẹ́ yìí ti kúrò lọ́mọ ìrákòrò, ó ti kúrò lọ́mọ àgbékọ́rùn roko. Ǹjẹ́ iwájú tí à ń lọ náà, a kò ní di èrò ẹ̀hìn láéláé. Mo kí gbogbo àwọn Ààrẹ tó ti jẹ ṣáájú mi, àwọn gan-an ni à bá máa pè ní èjìká tí kò jẹ́ kí ẹ̀wù ó bọ́ lọ́rùn. Àwọn ni àti ránmú gángan Ẹgbẹ́ yìí kò ṣẹ̀yìn  èékánná wọn nípa ìdàgbàsókè èdè àti àsà Yorùbá.

 

Bákan náà ni mo kàn sí gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ ní gbogbo àgbáyé fún akitiyan àti ìlàkàkà wọn lórí ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ni ìjọba ìbílẹ̀ àti ní ẹlẹ́kùnjẹkùn, lórí ìpàdé àpérò ẹlẹ́ẹ̀kan ní ọdún tí a máa ń ṣe, irú èyí tí a ń ṣe lọ́wọ́ yìí, àti nípàtàkì láti rí i pé èdè Yorùbá kò di àtẹ̀mẹ́rẹ̀ láàrin àwọn èdè àgbáyé. Ẹ ṣeun o.

 

Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àsà Yorùbá ti di igi àlọ́yè, ó ti di igi àràbà tí kò ṣe e fà tu, kò síbi tí ọwọ́jà kíkọ, kíkà àti lílò èdè Yorùbá kò dé ní gbogbo ayé. Èdè tó jẹ́ àtẹ́wọ́gbà gbáà ni. Mo sì ń fi àsìkò yìí kí gbogbo ọmọ káàárọ̀-o-ò-jíire àṣeyọrí yìí. A wá ń rọ àwọn Ẹgbẹ́ yòókù tí wọn ń tọpa ìdàgbàsókè àṣà, èdè àti ìṣe Yorùbá náà pé kí wọn wá darapọ̀ mọ́ wa kí á le túbọ̀ gbé èdè, àṣà àti ìṣe Yorùbá lárugẹ sí i.

 

Bí a ṣe pé bìbà síbí lónìí yìí, ohun tí ń bẹ lọ́kàn kálukú kò jọ ara wọn. Kò sí ẹni tí a ó bi tí kò ní rí wí. Sùgbọ́n nǹkan kan  tí yóò papọ̀ jù ni wípé, mo wá kọ́ ẹ̀kọ́ mọ́ ẹ̀kọ́, mo sì wá ní ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá, Nàìjìríà fi foríkorí, tí wọn fikùnlukùn pé ìmọ̀ àwà olùkọ́ gbọ́dọ̀ gbòòrò sí i lórí àwọn ìwé Lítíréṣọ̀ gbogbo ti àjọ WAEC àti NECO yàn fún àwọn ọmọ, tí a fi jáde pẹ̀lú Àkòrí ‘ÀTÚPALẸ̀ ÀWỌN ÌWÉ ÀṢÀYÀN TÍ ÀJỌ AṢÈDÁNWÒ WAEC ÀTI NECO (2016 - 2020)’ ní ọdún yìí. Ó dá mi lójú pé nígbà tí a bá padà délé, gbogbo àwọn ohun tó yẹ kí àwọn ọmọ yìí mò lórí àwọn ìwé àsàyàn wọ̀nyí ni a ó fi kọ́ wọn tí wọn yóò fi yege.

 

ÀṢEYỌRÍ

Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ Ọọ̀niriṣà, Ọba Okùnadé Síjúwadé Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ fún sarè ìlẹ̀ bíi mẹ́ta tí wọn fún wa láti kọ́ ilé ìyá Ẹgbẹ́ wa. Ọọ̀niriṣà mo kíi yín, ẹ ó pẹ́ fún wa, mo kí yín, ẹ o pẹ́ fún wa, a ó máà rí yín bá o. Àṣẹ a wa n fi àsìkò yìí rọ àwa ọmọ ẹgbẹ́ láti sowọ́pọ̀ kí ẹ gbàrùkù tí wá láti lè kọ́ ilé sí orí ilẹ́ náà. Nmi kété¸tí a bá ti pàrí àwòrán ilé náà ni yíyà, a nó ṣe ìfilọ́lẹ̀ náà rẹ̀ lágbárá èdùmàrè.

 

Ẹgbẹ́ akọ́mọlédè àti àṣà yorùbá tí dara pọ̀ mọ́ àwọn èdè míràn lágbàáyé tó ti fidìmúlẹ̀ láti máa ṣe ÀYÁJỌ́ ÈDÈ ABÍNIBÍ LÁGBÀÁYÉ. Ọdọọdún ni ayẹyẹ àyájọ́ yìí n gbòòreò sí i ni àwọn ìpínlẹ̀ wa gbogbo tí a sì n ṣe é tìlù-tìfọn. A n ṣe èyí kí èdè yorùbá nàá túnbọ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láarin gbogbo ènìyàn àti pé kí èdè miràn máṣe jẹ gàbà lórí èdè wa.

 

Láti bi ogójì ọdún tí a ti n ṣe ìpàdé yìí a dúpẹ́ pé àkàlàmàgbò wa kò pan ọdún jẹ rí. A dúpẹ́ fún aṣeyọrí yìí. Ọmọ ogóji ọdún kìí ṣe ọmọdé mọ́. Àṣeyọrí ńlá ni fún wa pé ẹgbẹ́ yìí kò yọ sọnù bíi ọmọ ọwọ̀. Ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ tó jọba láàrin wa kò lẹ́gbẹ́. Àdúrà wa ni pé Ẹgbẹ́ yìí yóò máa dàgbàsókè síi. Ewé ńlá wa kò ní padà rú wẹ́wẹ́ mọ́ láéláé. Àṣe.

 

ÌṢÒRO

A dára má kù síbìkan kò sí, òun la fẹ́ wí, ìṣòro ńlá ló ń dojúkọ ẹ̀kọ́-èdè Yorùbá ní orílẹ̀-èdè yìí bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì àgbà. Àìkọbiara ìjọba àpapọ̀ sí àwọn èdè abínibí ni ilẹ̀ wa lórí ẹ́kọ́ lo n jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn ipínlẹ́ ó máa fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú un. Ìlànà ètò ẹ̀kọ́ tí wọn ṣe ní ọdún 1976 ti wọ́n ṣe àtúnkọ rẹ̀ ní ọdún 1981 lá à kalẹ̀ pé ọ̀kan nínú èdè abínibí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí èdè Haúsá, èdè Ìgbò, àti èdè Yorùbá jẹ ọ̀ràn-an-yàn fún akẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì àgbà. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, ìjọba kò sì sọ̀rọ̀ mọ́, àjọ tó ń ṣe ìwádìí àti ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ (NERDC) tó jẹ́ ẹ̀ka kan lábẹ́ ilé-iṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ti ìjọba àpapọ̀ tún ń lo idà tirẹ̀ tí kò jẹ́ kí a le mọ́ odó tí a dọ̀rúnlá sí lórí àwọn èdè abínibí wa ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wa gbogbo. Àwọn òbí ò fi èdè Yorùbá bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ mọ́. Èdè gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń lò ní gbogbo ìgbà. Èyí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn òbí yìí ní wọ́n pa àmì ìdánimọ̀ wa rẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Yorùbá nítorí pé èdè jẹ́ àmì pàtàkì tí a fi ń dá ẹ̀yà kan mọ̀. Há a, ẹ̀yin ọmọ Yorùbá o, ẹ máṣe jẹ́kí á mú ara wa lẹ́rú lẹ́ẹ̀kejì o. Ẹ gbé èdè yìí lárugẹ. Bí a bá fojú wò ó, kò sí ohun tó ń jẹ́ òwe lẹ́nu àwọn ọmọ. Àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè ti di ohun ìgbàgbé. Agídí làwọn ọmọ fi ń kọ́ èdè Yorùbá láwọn ilé-ẹkọ́ wa gbogbo. Ìjọba kò sì fi bẹ́ẹ̀ gba àwọn olùkọ́ èdè Yorùbá ṣíṣẹ́. Níbo la wá ń lọ lórí àtijẹ́ kí èdè wa ó le túbọ̀ gbèrú sí i?

 

A wá ń késí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nífọ̀n-léèkánná láti bá wa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ìjọba wa gbogbo kí wọ́n má jẹ́ kí èdè Yorùbá ó di ohun ìgbàgbé. Yorùbá ló ni Àsà àti ìse, à ń rọ àwọn orí Adé wa gbogbo láti jáwọ́ nínú à ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì níbi ìpàdé wọn gbogbo. Ó ṣeeṣée láti wá ògbufọ̀ tí yóò máa bá yín gba ọ̀rọ̀ yín sọ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì tí ẹ bá gba àlejò láàfin yín, kì í ṣe àìgbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì yín la fi dá àbá yìí, ṣùgbọ́n kí èdè wa má ba à kú la fi sọ́. Àwọn ìjọba wa pàápàá gbọ́dọ̀ máa ṣe àmúlò èdè yìí níbi ìpàdé wọn gbogbo nítorí ìwọ̀nba èdè Gẹ̀ẹ́sí ni wọ́n sọ fáwọn aráàlú nígbà tí wọn ń tọ̀rọ̀ ìbò. È̀dè yìí ò gbọdọ̀ kú o.

 

Ẹgbẹ́ yìí ní ìsòro owó púpọ̀ ọ̀pọ̀, iṣẹ́ ní a fẹ́ ṣe láti mú kí ẹgbẹ́ yìí tẹ̀síwájú, sùgbọ́n àìsí owó ń já wa ní tànmọ́nọ̀n pàápàá láti kọ́ ilé Ìyá Ẹgbẹ́ wa lórí ilẹ̀ wa ni Ifẹ̀. Mo wá ń lo àsìkò yìí láti pàrọwà sí àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ láti san gbogbo owó tó yẹ kí á san nínú ìpàdé yìí. Bákan náà ni mò ń bẹ àwọn bàbá wa Kábíyèsí - Àwọn Orí Adé wa gbogbo láti bá wa kàn sí àwọn ọmọ ìlú wọn gbogbo tí orí ṣẹ́gi ọlà fún, tí wọn sì ní ìfẹ́ èdè Yorùbá láti ṣe àtìlẹyìn owó fún Ẹgbẹ́ yìí àti pàápàá sí àwọn Gómìnà wa gbogbo ní Ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.

 

ÌDÚPẸ́                                                                   

Lẹ́ẹ̀kan síi, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọlọ́lá Ajímọ̀bí àti àwọn ikọ̀ wọn pé wọ́n gbà wá láàyè láti ṣe ìpàdé Àpérò wá tí ọdún yìí ní Ìpínlẹ̀ wọn. A dúpẹ́ o, a ó máa ríi yín bá o. Ẹrù Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ẹ rù, Adẹ́ẹ̀dá yóò bá yín gbé e dórí, kò sí ni yẹ̀ ẹ́ lẹ̀.

 

Bákan náà ní ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ Bàbá wa Ṣọ̀un tí Ògbómọ̀sọ́ pẹ̀lú àwọn orí Adé gbogbo tó wá yẹ́ wa sí lónìí. A dúpẹ́ fún gbígbà tí ẹ gbà wá tọwọ́-tẹsẹ̀. Adé á pẹ́ lórí, bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀, ìrùkẹ̀rẹ̀ á di abẹ́rẹ́, ẹṣin ọba á jẹ oko pẹ́, àṣẹ á pẹ́ lẹ́nu kánrin-kése.

Mo fẹ́ lo àsìkò yìí láti dúpé lọ́wọ́ ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ yìí fún àyè tí wọ́n fún wa láti ṣe ìpàdé àpérò yìí ni ilé-ẹkọ́ yìí ìmọ́lẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ yìí kò ní wọ òòkùn.

 

Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ àwọn ilé-iṣẹ́ atẹ̀wétà, Macmillan, Evans, University Press, Learn Africa, Rasmed, Extension, Spectrum, abbl fún ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹyìn àtìgbàdégbà tí ẹ ń ṣe fún ẹgbẹ́ yìí. Ẹyẹ kìí fò kí ó forí sọgi, ìkọ́ kìí kọ́ ejò lọ́nà, òkè ní ẹ́ máa lọ o, àṣẹ. Ara ìwúrí tí ẹ ń ṣe fún Ẹgbẹ́ ló mú kí á rò pé kí á fi àmì ẹ̀yẹ dá yín lọ́lá lónìí láti fi sàmì àyẹyẹ ìpàdé Àpérò ológójì ọdún tí à ń ṣe lónìí. Ilé-iṣẹ́ yín gbogbo yóò máa gbèrú sí i. Àṣẹ.

 

Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè lápapọ̀, ní pàtàkì jùlọ àwọn ọmọ Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ yìí ní ìpínlẹ̀ wa gbogbo àti ní ìpínlẹ̀ yìí fún ìlàkàkà wọn tó mú kí ìpàdé yíì ó dùn tó sì lárinrin. N kò ní sàì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀yin ìrírí dọgbọ́n wa gbogbo, ẹ̀yin àgbà Ẹgbẹ́, àti ẹ̀yin olùbádàmọ̀ràn Ààrẹ Ẹgbé yìí. Ẹ ṣeun-un o, iwájú ni ojúgun ń gbé, iwájú lẹ ó máa lọ.

 

ÌGÚNLẸ̀

Ní àkótán, mo kí gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ pé a kú ọdún, a kú ìyèdún, ẹ̀mí á ṣe púpọ̀ rẹ̀ lókè eèpẹ̀. A sì kú àpérò. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀mí ìṣọ̀kan, ìgbọ́ra-ẹni-yé, àti ìfaradà ó jọba lọ́kàn gbogbo wa. Ẹ jẹ́ ká fí ara wa ṣe òṣùsù ọwọ̀ lásìkò ìpàdé yìí àti lẹ́yìn ìpàdé, kí á ba à lé jẹ́ àwòkọ́ṣe fún gbogbo àwọn Ẹgbẹ́ mìíràn. Kí a sì fi ara balẹ̀ láti gbọ́ gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa.

 

Ẹ ṣeun o

Mo dúpẹ́ fún sùúrù yín látàárọ̀

Ojú wa yóò máa rọ́dún o, nítorí pé:

Ọdọọdún nilá ń sogún

Ọdọọdún ni àwọn nkàn

Ń so lọ́gbọ̀n-lọ́gbọ̀n

Ẹgbẹ́ wa ò ní pọ̀ ìpọ̀ àìṣí èrè

Àkàlàmàgbò wa kò ní pọdún jẹ

Àṣèyí ṣàmọ́dún láṣẹ Èdùmàrè

Akọ́mọlédè – Tiwa làṣà Ọmọlúàbí

Akọ́mọláṣà – Tiwa lèdè Ọmọlúàbí.

 

--------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------

Ọ̀RỌ̀ ÌKÍNI KÚ ÀBỌ̀ SÍBI AYẸYẸ ÀJỌ̀DÚN OGÓJÌ ỌDÚN ÀTI ÌPÀDÉ ÀPÉRÒ ỌLỌ́DỌỌDÚN TI ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀṢÀ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, TÍ Ó WÁYÉ NÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́

“FEDERAL GOVERNMENT COLLEGE” ÒGBÓMỌ̀ṢỌ́,

NÍ ỌJỌ́ KẸTA SÍ ỌJỌ́ KEJE, OṢÙ KẸJỌ, ỌDÚN 2014

LÁTI ẸNU DÍÁKÓNÌ MATTHEW KỌ́LÁWỌLÉ ÒGÚNKÚNLÉ

(ALÁGA ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́)

 • Mo kí Ọlọ́lá Sẹ́nátọ̀ Abíọ́lá Adéyẹmí Ajímọ́bi (Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́), 
 • Ààrẹ Ẹgbẹ́, Àlùfáà Ayọ̀ Adésínà,
 • Abẹnugan Ilé Ìgbímọ́  Aṣòfin; Mọnsurat Aya Sùnmọ́nù;
 • Kọmísánnà náà fún Ètò Ẹ̀kọ́ ní Ọ̀yọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Solomon Ọláníyọnu;
 • Orí Adé, Ọba Aláyélúwà; Ọba Jimọh Ọládùnní Oyèwùmí Ajagungbadé III (JP) CON. Sọ̀ún ti Ilẹ̀ Ò́gbómọ̀ṣọ́.
 • Alága Ìjọba Ìbílẹ̀ ATISBO, Amòfin Jacob, Fúnmi Ògúnmọ́lá,
 • Olùsọ̀rọ̀ Pàtàkì Òj̣ọ̀gbọ́n Dúró Adélékè,
 • Gbogbo ẹ̀yin Àlejò pàtàkì pàtàkì,
 • Gbogbo ọmọ ìgbìmọ̀ àpapọ̀ Ẹgbẹ́
 • Ọmọ ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣa káàkiri Orílẹ̀ – Èdè Nàìjíríà,
 • Gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Mo kí wa kú àbọ́ sí ìpàdé àpérò ti ọdún yìí. A kú ọjọ́ méji, jọ mẹ́ta, ilé ò dáa bí? Ọ̀dẹ̀dẹ̀ ò sunwọ̀n? Ẹni tí a bí tilẹ́ ti rí ní ìta tó ń jó; ilé dára tàbí kò dàra ti kúrò lọ́rọ̀ onítọ̀hún yẹn; ilé wa yóò máa rójú, ọ̀ọ̀dẹ̀ wa yóò máa tòrò; ilé tó sì dára tí a fi sílẹ̀, àìrójú kò ní wọlé ọ̀hún lẹ́yìn wa.

 

Ọjọ́ ọ̀hún náà nìyí bí àná yìí, tí a fi ẹgbẹ́ yìí lọ́lẹ̀ ní nǹkan bíi Ogójì Odún ó lé márùn-ún sẹ́yìn lábẹ́ Ààrẹ àkọ́kọ́;  Olóyè Akínbọ̀wálé ní ílù Ìbàdàn, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a sì ṣe àpérò àkọ́kọ̀ ni Ogójì ọdún sẹ́yìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yìí náa. Ó yẹ kí á kíra wa kú oríire wí pé, èṣo wóró músítádì tí àwọn bàbá yìí gbín lọ́jọ́ náà. Àwọn bíi Olóyè E.D. Akínbọ̀wálé, Alàgbà Adétúnjí; Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọ́táyọ̀ aya Olútóyè, Olòògbé Àlàájì Oyèbánjí Mustapha, Olóyè Délé Àjàyi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúgbóyèga Àlàbá, Ọ̀mọ̀wé Adémọ́lá, Ọdẹ́tókun àti àwọn àgbà ẹgbẹ́ tó ti sùn àti àwọn tó sì wà láyé ló di igi Àràbà lónìí yìí o; Ẹ ò sì tún ríì bí ìtàn kò ṣe ṣe òjóóró; nígbà tí a ó tún ṣe ayẹyẹ Ogójì Ọdun, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà ló tún bọ́ sí; A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba.

 

Mo bá Gómìnà Olóríire wa ní Ípínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yọ̀ wí pé àwọn nǹkan ìtàn málegbàgbé ló ń ṣẹlẹ̀ ni akókò tiwọn. Mo rántí pé láìpẹ́ yìí náà ni wọ́n gba àlejò gbogbo àwọn ọ̀gá Ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì kààkiri Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìlú Ìbàdàn. Ní àsìkò tíwọn ni ìjọ Onítẹ̀bọmi ní Orílẹ̀ – èdè Nàìjíríà ṣe ayẹyẹ Ọgọ́rùn-ún Ọdún ní ilú Ìbàdàn, fún ìgbà àkọ́kọ́, àsìkò wọn ni Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn pé Ọgọ́rún-ún ọdún tí wọ́n sì ṣe ayẹyẹ rẹ̀ ní Ìbàdàn; A ò fi wọ́n ṣe ẹlòmíràn lónìí, tí wọn tún ń fojú rí ayẹyẹ Ogójì ọdún tí ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà ní Orílẹ́-èdè Nàìjíríà ní Ilú Ògbómọ̀sọ́. Oríire náà yóò máa tẹ̀síwájú.

Ẹyin Ọmọ ẹgbẹ́ lápapọ̀; Ọ̀kan nínú ìdí pàtàkì tí a fi pe Abẹnugan Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá síbí láti yẹ́ wọn sí ni wí pé;

 1.  Nígbà tí ìjọba àpapọ̀ gbé àbá kan dìdé nínú ètò ẹ̀kọ́ wí pé, Èdè Yorùbá kò jẹ́ kàn-ń-pá fún àwọn aṣèdánwò WASCE àti NECO mọ́, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yó, lábẹ́ ìdaríi Gómínà wa ni ó kọ́kọ́ ta kòó, tí wọ́n si sọọ́ di òfin ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wí pé, gbogbo aṣègánwò WASCE àti NECO yálà ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ndírí tí Ìjọba tàbí ti Aládàni gbọ́dọ́ máa ṣe Èdè Yorùbá.
 2. Wọ́n pa láṣẹ wí́ pé gbogbo ọmọ tí yóò bá gba iṣẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ iwàjù gbọ́dọ̀ ṣe àṣeyege nínú èdè Yorùbá.
 3. Wọ́n fi kún un pé ní gbogbo Ọjọ́ rú, èdé Yorùbá ni gbogbo Ilé-èkọ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbọ́dọ̀ máa fi kọ Orin orílẹ̀-èdè wa àti kíka ẹ̀jẹ́.
 4. Ilé Ìgbìmọ̀ aṣofin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gan-an yóó máa lo èdè Yorùbá fún gbogbo ètò wọn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ó kéré jù, ẹ̀ẹ̀kan lóṣẹ̀.
 5. Bí ẹ wo ìwọṣọ Gómínà wa; Àwọn ọmo ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àti gbogbo àwọn tí ń sètò ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti Ọmọlúàbí ni.

 

Ẹ̀yin àgbà lẹ sọ pé, “ìrèere tó ń jó lójú omi, Onílùú rẹ̀ wà nísàlẹ̀ odò” yàtọ̀ sí wí pé Arábìnrín yìí ni Obìnrin àkọ́kọ́ tí yóó darí ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Òun náà ni atọ́kùn àlàáfíà nínú ilé ìgbìmò aṣòfin torí pé láti ìgbà tí ìjọba yìí ti bẹ̀rẹ̀, kò sí gbọ́n mi-síi, omi-ò̀-tóo ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yó.̣

 

Àwòkọ́ṣe Gómìnà Abíọ́lá Adéyẹmí Ajímọbi ni Kọmísánà fún Ètò ẹ́kọ́ náà ń tẹ̀ lè ìgbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Solomon Ọláníyọnu ti dé , ni Ètò-ẹ̀kọ́ tí n tẹ̀síwájú ni gbogbo ọ̀nà. Ni ti Họṇrébù Jacob Fúnmi Ògúmọ́lá, tẹ̀tẹ̀ pòpó ti lomi tẹ́lè kí òjò tóó dé ni ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kí á tóó yàn án gẹ́gẹ́ bí Alága A-fún-nṣọ́ ní ó ti nífẹ̀ẹ́ sí ètò ẹ́kọ̀; tí ó sí ń ṣe kóríyá fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìjọba Ìbílẹ̀ Atisbo àti Òkè-Ogún lápapọ̀.

 

Oun ni Olùdásílẹ́ “Ogúnmọ́lá Foundation” tí ó pe àlàjẹ́ rè nì  “ìgbé ayé ìrọ̀rùn fún àwọn ènìyàn mi” Láti ọdún ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀.

Ní ọdún 2012, àti 2013, Ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí Ọgbọ̀n ní ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ ní jọba ìbílẹ̀ ATISBO, Ó sì fún àwọn opó ní jọba ìbìlẹ̀ ATISBO, ìla-òòrùn Ṣakí àti Ìwọ̀- Oòrùn Ṣakí ní ẹbùn tó jọjú.

Ní ọdún 2014 yìí, Aké̀kọ̀ọ́ bíi mẹ́rìn-lé-láaàádọ́fà (114 students) káàkiri Ilẹ́-ẹ̀kọ́ sẹ̀kóndírì ní òkè-ògùn ni ó fún ẹ̀bùn èkọ̀ ọ̀fẹ́ yìí, ó sì fún àwọn opó bíí ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta ní gbogbo Ìbìlẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó wà ní Òkè-Ògùn ní irú ẹ̀bùn yìí kan náà:

Alága yìí kọ́ yààrá ìkàwé sí gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì ti ìjọba ní ìjoba Ìbílẹ̀ ATISBO. Bákan náà, ógbẹ́  kànga-dẹ̀rọ (bole-hole) sí gbogbo àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ndírí yìí.

Bẹ́ẹ̀ ló ma ń ṣe kóríyá  lóórèkóórè fún àwon ọ̀gá Ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo nígbà tí wọ́n bá ń lọ síbí àpéro  ọlọ́dọọdún, àti iṣẹ́ mìíràn tí a ò le máa kà tán lẹsẹẹsẹ.

A kíyèsí i wí pé, kò si ohun tí ó le mú kí ènìyàn máa ṣe eléyìí bí kò bà jẹ́ ọmọlúàbí ènìyàn, torí pé ọ̀kan lára ohun tí ẹgbẹ́ yìí ń gbé lárugẹ ni ìwà Ọmọlúàbí, a wòye pè wọ́n yẹ ní ẹni tí ó yẹ, kí á dá lólá.

 

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọ̀rọ̀ kábíyèsí Sọ̀ún ti ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́ rí; òótọ́ ni wí pé bí ìlú bá ń tòrò, tí ó ń dàgbà síi, tí nńkan rere sì ń sẹlẹ̀ níbẹ, kí á mọ́ wí pé loĺríire ọba ni wọ́n ní; Àsìkò bàbá yìí  ń tùbà, ó sì ń tùsẹ, ní agbára Ẹlẹ́dàá, ẹ ó gbòó, gbòó gbòó olúogbó, ẹ ó dàgbà dàgbà, olúyẹ̀yẹ̀-ǹ tuyẹ̀. Èyí tó gbógbòógbó tó fọmọ owú ṣe ońdè sọ́rùn, omo owú jẹ jẹẹ jẹ kù bí abẹ́rẹ́, abẹ́rẹ́ jẹ jẹẹ jẹ kù bí ìrú ẹṣin.

Adé yòó pẹ́ lórí, ìlẹ̀kẹ̀ yòó pẹ́ lọ́run, ẹ ó fi èrìgì jobì, ẹsin ọba yóò sì jẹko pé.

          Mo kí Àarẹ Ẹgbẹ̀ àti gbogbo ọmọ ìgbìmọ̀ rẹ̀, kú oríire lónìí, Yorùbá bọ̀; wọ́n ní ojú tí yóò ba bá ni kalẹ́, kò nìí tàárọ̀ yọ ipin; oríire tí ẹ fi bẹ̀rẹ̀ yìí yóò tẹ̀síwájú lágbára ọlórun.

          Ìpàdé àpérò ti ọdún yìí àrá ọ̀tọ̀ ni, bí a bá ṣe eré òkòtó débi tí à ń dáràá konko, eré ṣetán tí yòó túká ni; ní àsìkò tiyín yìí, àràa tùjẹ̀ ni a ó maa dá; ara yóò máa tu gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pẹ̀sẹ̀; gbogbgo àfojúsùn ẹgbẹ́ yóò sì máa jẹ́ síṣe.

          Ní orúkọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ni mò ń kí wa káábọ̀ sí ìpadé àpérò ti ọdún yìí; Ní agbára Ẹlẹ́dàá, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmí Ìsọ̀lá ṣe sọ nínú Ìwé Ewìi rẹ̀ “Àfàìmọ̀ àti àwọn àròfọ̀ mìíràn” ó ní:

“Kò ṣéléré ehoro,

Kò sólókìtì ìjímèrè,

Kò sírú u kánún láárin òkúta,

Kò sírú iyọ̀ léépẹ̀   

Eégun tó le jó bíi lébe ò sí mọ́”

Kò tún sí okùn mìíran nígbó mọ́

Báa bá ti yọwọ́ ọ kán-ànrán-jangban

Kò tún ṣegbẹ́ẹ mìíran

Tí ìmọ̀ wọn le jọ tí yóò sì sọ̀kan,

Bí ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá

Lọ́lá Ẹlẹ́dàá; Iwájú ni ojúgun ún gbé

Iwájú ni Èdè Yorùbá yóò máa lọ. Àṣẹ.

 

Tóò, bí ọbẹ̀ kò tilẹ̀ dùn, à maa torí àníyàn jẹẹ́, gbogbo kùdìẹkudiẹ tó bá kù nínú ètò wa, ẹ bá wa fi ṣosùn, kí ẹ fi kunra; A kìí mọ ọ́n gún mọ̀ ọ́n tẹ̀ kí iyán ewùrà má léenmọ́; mo gbàgbọ́ wí pé tí tí a ó fi parí àpérò yìí, ire lojú owó ó rí, iré la ó fojú wa rí o.

Ẹ ṣeé, Ẹ káàbọ̀.

Reviewed Publications

 • Ise Yoruba - Reviewed by Sobande Seyi
 • Asa ati Ede - Reviewed by Adedigba Sylvester
 • View All →

  Subscribe to Our
  Newsletter

  Quotable Quote

  The only person that is educated is the one that has learned how to learn and change. - Carl Rogers

  Ọwọ́ ọmọdé kò tó pẹpẹ ti àgbàlagbà kò wọ kèrègbè

   

  Ewé kì í bọ́ lára igi kó ni igi lára ----- the dropping of a leaf off a tree presents no burden to the tree.

  © 2022 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Naijiria. All Rights Reserved.