Èkìtì 2018 |
Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ Ààrẹ Díákónì Ọmọ́wùmí aya Fálẹ́yẹ Mo júbà Ọlọ́run Olódùmarè. Mo júbà gbogbo ẹ̀yin àgbààgbà Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Mo kí ẹ̀yin ìgbìmọ̀ tí ẹ ti ń tùkọ̀ ẹgbẹ́ yìí bọ̀ ṣaájú àkókò yìí. Ayọ̀ àti ìdùnnú ìgbìmọ̀ wa ni láti rí ibi tí àwọn aṣaájú wa tukọ̀ ẹgbẹ́ yìí dé pẹ̀lú ìlérí àtìlẹyìn gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láti ṣàtìlẹ́yìn ìtẹ̀síwájú rere fún ìgbìmọ̀ wa. Mo ṣèbà gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè lọ́kùnrin àti lóbìnrin jákè-jádò àgbàláayé fún ìnáwó-nára pẹ̀lú àtìlẹyìn fún Ẹgbẹ́ yìí. Kò ní í sú waá ṣe o. Lóòótọ́, Ọlọ́run àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹgbẹ́ yìí yàn mí gẹ́gẹ́ bí Ààrẹbìnrin kejì láti tukọ̀ egbẹ́ wa yìí síwájú .Mo wá fi àsìkò yìí rọ̀ wá láti jọ̀wọ́ fọwọ́sowọ́pọ̀ mú àkọ̀tun ìtẹ̀síwájú bá ẹgbẹ́ wa.A o máa fi ọ̀rọ̀ wa lọ ẹ̀yin àgbà.Mo si gbàdúrà fún wa pé Ọlọ́run yóò ran ẹ̀yin àgbà wa lọ́wọ́ láti tọ́ wa sọ́nà bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ,láti mú èròǹgbà wa ṣẹ fún ìyìnlógo Ọlọ́run àti ìdàgbàsókè Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá Nàìjíríà. Ayọ̀,ìbùkún àti ojúrere Olódùmarè kò ní í dásẹ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pátá. Ire o!!! Díákónì Ọmọ́wùmí aya Fálẹ́yẹ Ààrẹ Ẹgbẹ́
Ìṣípàdé ní Ọjọ́ Ajé (6/8/2018)
Ìwúre Ìṣíde láti ẹnu Olóyè Diípọ̀ Gbénró (Ààrẹ Ìjẹta)
Ọ̀rọ̀ Aṣojú Ọba Ọọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 1
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 2
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 3
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 4
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 5
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 6
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 7
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 8
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ 9
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Kogí 1 Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Kogí 1
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Àbújá 1
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Àbújá 2
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Àbújá 3
Alẹ́ Ìpínlẹ̀ – Ìpínlẹ̀ Èkó 1 |